Hymn 29
Ati lati duro li orowuro lati dupe, ati lati Yin Oluwa ati be gege li asale.
Meter: 9.8.9.8
Scripture: I Kro. 23:30
1
mfOluwa, ojo to fun wa pin,
Okunkun si de l’ase Re,
‘Wo l’a korin owuro wa si,
Iyin Re y’o m’ale wa dun.
2
mfA dupe ti ijo Re ko sun,
B’aye ti nyi lo s’imole,
O si nsona ni gbogbo aye,
Ko si simi t’osan-t’oru.
3
B’ile si ti nmo l’ojojumo,
Ni orile at’ekusu,
Ohun adura ko dake ri,
Be l’orin iyin ko dekun
4
Orun t’o wo fun wa, si ti la,
S’awon eda iwo-orun,
Nigbakugba li enu si nso
Ise ‘yanu Re di mimo
5
crBe, Oluwa, lae n’Ijoba Re,
Ko dabi ijoba ye;
FO duro, o si nse akoso,
Tit’ida Re o juba Re.