Hymn 291
Hosanna fun Omo Dafidi
Meter: C.M.
Scripture: Mat.21:9
1
f“Hosana s’Omo Dafidi:”
ffHosana! e korin!
“Olubukun l’ eni ti mbo
Loruko Oluwa.”
2
f“Hosana s’Omo Dafidi”:
L’egbe Angeli nke;
ffGbogb’eda, e jumo gberin,
Hosana! s’Oba wa.
3
Hosana! awon Heberu
Ja im’ope s’ona;
Hosana! a mu ebun wa
Fi tun ona Re se
4
ffT’agba t’ewe nke, Hosana!
pKijiya Re to de;
L’oni, a si nko Hosana!
B’o ti njoba loke.
B’o ti gba 'yin won nigbana,
pJo, gba ebe wa yi
Lorun, k’a le b' Angel’ korin,
ffHosana s’Oba wa