Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 292

Nitori irapada okan WON iyebiye ni.

Meter: 9.8.9.8. & Ref.

Scripture: OD. 49:8

1

fIrapada! itan iyanu,

Ihin ayo fun gbogbo wa,

Jesu ti ra ’dariji fun wa,

O san ’gbese na lor’igi.

CHORUS

ffA! elese gba ihin na gbo,

Jo gba ihin oto na gbo,

Gbeke re le Olugbala re

T’O mu igbala fun o wa.

2

mpOmu wa t’inu’ku bo si’ye,

O si SO wa d’om’Olorun;

crOrisun kan si fun elese

We nin’eje na ko si mo

3

fEse ki y’o le joba wa mo

B’o ti wu ko dan wa wo to,

Nitori Kristi fi ’rapada

Pa ’gbara ese run fun wa.

4

fGba anu t’Olorun fi lo o.

Sa wa s’odo Jesu loni

’Tori y’o gb’eni t’o ba t’o wa

Ki yi o si da pada lae