Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 3

Emi tikara mi yio si ji ni kutukutu.

Meter: L.M

Scripture: OD 108:2

1

fJi Okan mi, ba orun ji,

Mura si ise ojo Re.

Mase ilora, ji kutu.

K’o san ‘gbese ebo oro

2

Ro gbogb’ojo t’o fi sofo

Bere si rere ‘se loni

Kiyesi ‘rin re l’aye yi,

Ko si mura d’ojo nla ni.

3

mfK’oro re gbogbo j’otito,

K’okan re mo b’osan gangan

Mo p’Olorun nso ona re

O mo ero ikoko re.

4

fNipa ‘mole ti nt’roun wa

Tan ‘mole na f’elomiran

Jeki ogo Olorun ‘han

Ninu ife at’orun yin

5

fJi, gbonranu ‘wo okan mi,

Yan ipo re l’arin angeli’,

Awon ti won nkorin iyin

Ni gbogbo igba s’Oba wa.

6

fMo ji, mo ji, ogun orun,

Ki isin yin s’okan mi ji,

Ki nle lo ojo aye mi,

Fun Olorun mi bi ti yin.