Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 300

On o ru aisedede won wonni.

Meter: 8.7.8.7.D.

Scripture: Isa. 53:11

1

mpW ’Olori Alufa giga,

B’o ti gbe ebe wa LO;

pL’ogba O fikedun wole

O feru d’oju bole;

Angeli fidamu duro

Lati ri Eleda be;

crAwa o ha wa l’aigb’ogbe,

T’a mo pe ’tori wa ni?

2

mfKiki eje Jesu nikan

L’o le yi okan pada;

On lo le gba wa n’nu ebi,

On lo le m’okan wa ro;

Ofin at’ikilo ko to,

Won ko si le nikan se;

crEro yi lo m’okan ro;

Oluwa ku dipo mi;

3

mfJesu, gbogbo itunu wa,

Lat’ odo Re lo ti nwa;

crIfe, gbagbo, ’reti, suru.'

Gbogbo re l’eje Re ra;

fLat’ inu ekun Re l’a ngba,

A ko da ohun kan ni;

L’ofe n’iwo nfi won tore

Fun awon t’o s’alaini.