Hymn 302
Eje Kristi iyebiye.
Meter: 6.5.6.5.
Scripture: I Pet. 1:19
1
O go ni fun Jesu
pT’O fi ’rora nla
crTa eje Re fun mi
Lati iha Re.
2
fMo r’iye ailopin
Ninu eje na;
Iyonu Re sa po,
Ore Re ki tan!
3
fOpe ni titi lae
F’eje ’yebiye
T’Ora aye pada
Kuro n’nu egbe.
4
mfEje Abel’ nkigbe
Si orun f’esan;
Sugbon eje Jesu nke
fFun ’dariji wa.
5
pNigbati a bu won
Okan ese wa,
Satan, n’idamu re
fF’eru sa jade.
6
fNigbat’ aye ba nyo,
T’o n gbe ‘yin Re ga;
AWON ogun angel'
A ma f’ayo gbe
7
fNje egb'ohun yin ga,
Ki iro na dun!
ffKikan l’ohun Koto
Yin Od’agutan.