Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 310

Sugbon ki a mase ri pe, emi nsogo Biko se ninu agbelebu Jesu Kristi Oluwa wa.

Meter: L.M.

Scripture: Gal. 6:14

1

mf‘Gbati mo ri agbelebu

Ti a kan Oba Ogo mo

Mo ka gbogbo oro s’ofo

Mo kegan gbogbo ogo mi.

2

crK’a mase gbo pe mo nhale

B’o ye n’iku Oluwa mi

Gbogbo nkan asan ti mo fe

Mo da sile fun eje Re

3

pWo, lat’ ori, OWO, ese

B’ikanu at’ife ti nsan;

cr’Banuje at’ ife papo,

A fegun se ade ogo

4

mfGbogbo aye ’baje t’emi.

Ebun abere ni fun mi;

fIfe nla ti nyanilenu

Gba gbogbo okan, emi mi.