Hymn 314
Baba Dariji won nitori ti n won Ko mo ohun ti nwon nse
Meter: 7.7.7.6.
Scripture: Lk. 23:34.
mf‘Wo t’O mbebe f’ota Re,
L’ori ’gi agbelebu;
Wipe, “Fiji won, Baba”,
pJesu, sanu fun wa.
mfJesu jo bebe fun wa,
Fun ese wa ’gba gbogbo,
Ako mo ohun t’a se;
pJesu, sanu fun wa.
mfJe k’awa ti nwa anu
Dabi Re l’okan n’iwa,
Gbat’ a ba se wa n’ibi;
pJesu, sanu fun wa.
mfJesu,’Wot’O gbo aro
Ole t’o ku l’egbe Re.
T’O si mu d’orun rere
pJesu, sanu fun wa.
mfNinu ebi ese wa,
Je k’atoro anu Re;
K’a ma pe oruko Re,
pJesu, sanu fun wa.
mpRanti awa t’o nrahun,
T’a nwo agbelebu Re,
F’ireti mimo fun wa,
pJesu, sanu fun wa.
mf’Wo t’O fel’afedopin
Iya Re t’o nkanu Re
Ati ore Re owon;
pJesu, sanu fun wa.
mfJeka pin n’nu iya Re,
Ka ma ko iku fun O,
crJek’ari’toju Re gba;
crJesu, sanu fun wa.
fKi gbogbo awa Tire,
Je omo ile kanna;
crTori Re ka fe ’ra wa;
pJesu, sanu fun wa.
mfJesu ’Wo ti eru mba,
’Gbat’ O si ku ’WO nikan
crTi okunkun su bo O,
pJesu, sanu fun wa
mf’Gbati a ba npe lasan,
T’ireti wa si jina,
N’nu ok un na di wa mu.
pJesu, sanu fun wa
mfB’o dabi Baba ko gbo,
B’o dabi ’mole ko si,
Jeka f’igbagbo ri O.
pJesu, sanu fun WA
mfJesu, ninu ongbe Re
Ni ori agbelebu,
cr’WO ti O fe wa sibe,
pJesu, sanu fun wa.
mfMa k’ongbe fun wa sibe,
Sise mimo l’ara wa;
Te ife Re na l’orun;
pJesu, sanu fun wa.
mjJeka kongbe ife Re
Ma s’amona wa titi,
Sibi omi iye ni,
pJesu, sanu fun wa.
mfJesu Olurapada,
’Wo t’Ose’fe Baba Re,
T’O si jiya tori wa
pJesu, sanu fun wa.
mfGba wa l’OJO idamu,
Se Oluranlowo wa,
Lati ma t’ona mimo,
pJesu, sanu fun wa.
mfF’imole Re s’ona wa
Ti yo ma tan titi lae,
Tit’ ao fi de odo Re;
pJesu, sanu fun wa
mfJesu, gbogbo ise Re,
Gbogbo idamu Re pin,
fO jow’ emi Re lowo
pJesu sanu fun wa
mp’Gba ti ’ku bu de ba wa,
Gba wa lowo ota wa,
fYo wa ni wakati na,
pJesu, sanu fun wa.
Ki iju at’iye Re,
Mu ore ofe ba wa,
TI yio mu wa doke,
pJesu, sanu fun Wa