Hymn 315
ITAN ORI AGBELEBU Won o ma wo eniti a gun li oko.
Meter: 10.9
Scripture: Jn. 19:37
pN 'iwaya ’Jakadi,
On nikan nja,
O n fe iranlowo
sugbon ko ri.
B’osupa ti nwo
l’or’oke Olif,
Adura tani ngoke
l’oru yi?
Eje wo l’eyi ti nro bi ojo,
Lat’okan Re wa, “Eni ’banuje”
Irora ailese
mbe l’oju Re,
Ojiya ti mbebe, tan’ Iwo?
mpGbo b’O ti mba o so
’ro lokan re
“Omo ti mo ku fun
tele mi”
“Ki nma m’ago ti
Baba fun mi bi
’Gbati mimu re je”
’gbala re
“A lu, a tuto si,
a fi s’efe;
A na, a si de
l’ade egun.
“Mo nlo si Golgota
nibe, Uno ku,
cr’Tor’ ife Misi o
Emi ni.
mpA kan mo ’gi esin,
ko ke rora,
O r’eru wa,
’Tire ko.
’Wo orun mi ole
wo okun bi?
Oro wo lo nte
’nu Re wa ni
“Baba dariji won
l’adura Re,
crBaba si gbo, bi
’ti ma gbo’ri.
Gbo bi ole ni ti
ntoro anu;
mfOn se 'leri Pa
radise fun.
Ibatan at’ore
rogba yika,
Maria on Magdalen ropin re.
Meji ninu won di
tiya t’omo,
Okan t’oro Re
ti so d’okan.
pOkunkun bo ile
osan d’oru,
Iseju koja b’
odun pipo.
ppGbo ’gbe ’rora lat’ i
nu okun na
“Baba, ’Wo ko mi
sile ese?”
A! ikosile nla
iku egun!
Igbe kil’eyi,
“Ongbe ngbe Mi”!
crGbo “O ti pari”
Ijakadi pin,
Iku at’ipoku,
a se won.
p“Baba, gba emi mi,”
L’o wi keyin,
Krist’ Oluwa iye
O si ku.
mp“O mo ’rora mi ti
mo feje ra,
Mo gba o low’esu, f’ Olorun;
cr“Wa alare, wa f’ori
laya mi,
Sapamo sodo mi,
ko simi.
mf“Wa sodo Baba mi,
wa laiberu.
Alagbawi re,
wa nitosi.
“Wa mu ninu ore
ofe emi;
Emi ni ini re
’Wo t’emi.
mfM o fara mi fun O
Oluwa mi,
Sa fi ’fe Re ’yebiye fun mi.
mfGbogb’ohun ti mo ni
t’ara t’okan
Nko je fi du O
gba gbogno re
crSa ba mi gbe dopin
Oluwa mi,
Jesu, Olugbala
Oluwa mi
B’a koko Re ba de
Je ki nyin O
Yin O nile Re
titi laelae