Hymn 319
Kristi Jesu, eniti Olorun fi fe Ogbon ati ododo, ati isodi mimo ati idandefun wa.
Meter: L.M.
Scripture: IKor. 1:30.
1
mfJesu, eje ododo Re
Li ewa ati aso mi;
Bi mba WO won, b’aye ngbina
fUno f ayo gb’ori mi soke.
2
fUno ni ’gboya l’ojo ’dajo;
Tani ’ba ka si mi lorun?
A we mi mo patapata
Kuro l’ese, l’eru, l’ebi.
3
mpAlailegan Od’agutan
T’O t’okan-aya Baba wa,
T’O ku lati setu fun mi,
Ni mo yan ni Olorun mi.
4
mpOluwa, emi gbagbo pe
Eje Re nib’ite-anu
Ti nsipe lae fun elese
pL’a ta sile fun emi mi.
5
mfOluwa, mo si gbagbo pe
B’elese Po bi iyanrin,
’Wo ti ra gbogbo wpo pada,
cr’Wo ti setu fun gbogbo won.
6
mf’Gba mba jinde ninu oku
Lati gba ’bugbe mi lorun,
Eyi ni yo je ebe mi,
pJesu w’aye, O ku fun mi.