Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 321

Li ojo ti mo kepe, iwo da mi lohun, Iwo sifi ipa mu mi lara le li okan.

Meter: 11.11.11.77. & Ref.

Scripture: OD. 138:3.

1

mfMo nko ’rin ti Eni t’o gb’emi mi la,

Mo ro m’Ore na to so mi di pipe,

Ni ’daniloju pe nigba mba dele

Lojukoju ni uno ri.

CHORUS

fLojukoju ni uno ri,

Mo gbekel’ or’ofe Re,

Nipari ’rin ajo mi,

Lojukoju ni un o ri.

2

crMo ngbe ’nu eni Kanna ti mo njuba

Lojojo ni mo si nrohin ore Re,

Pe lehin gbogbo idanwo aye yi,

Lojukoju ni un o ri.

3

mfMo ngbe ninu ’mole orun ife Re,

Mo si nka fun ojo ’kore ti oke,

Ti mo ba si je ojo tito nihin,

Lojukoju ni un o ri.

4

fNiwaju Re, mo nri alafia pipe,

Itan Re mu ’nu gbogbo eniyan dun,

Ni ’daniloju pe nile wa loke

Lojukoju ni un o ri.