Hymn 325
Ko si nihin yi, sugbon O jinde.
Meter: 6.6.6.6.8.8.
Scripture: Lk. 24:6.
1
mfPelu iye didan
L’oro kutukutu,
L’angeli sokale,
crO y’okuta kuro.
fE jumogb’ohun yin
E yin Oluwa t’O Jinde
2
mf’Gbat’ awon oluso
Ri iran eru na
Won subu lojiji,
Won si dabi oku.
3
crO nde n’isu oku,
Oju eda ko ri;
O segun Iboji,
Oluwa gbogb' aye
4
crEyin omo ’mole,
E nde pel’ Oluwa;
Wo bi irawo Re,
Ti ntan l’oju orun
5
mpFi ohun atijo
Sile ninu ’boji,
A sin yin n’nu Jesu,
Eba jinde loni.
6
A yin O Oluwa,
Pelu agbara wa
N’tori a je Tire,
’Wo si je tiwa lae.