Hymn 326
Nwipe, Oluwa jinde, nitoto, O si tifi ara han fun Simoni.
Meter: S.M.
Scripture: Lk. 24:34.
1
fOluwa ji loto
Ise ‘gbala pari,
A tu awon onde sile,
A si s’ete iku
2
f“Oluwa ji loto”
Esu so tire nu,
Awon t’ara ji pelu Re
Lati joba laelae.
3
f“Oluwa ji loto”
O mbe, ko ni ku mo,
O mbe, lati be f’elese
Ti O ru egun won
4
f“Oluwa ji loto”
Eyin Angeli gbo
S’agbala orun, e sare,
Mu ‘hin ayo na lo.
5
ffE mu duru wura
K’e si te ’rin didun!
Eyin egbe orun dapo
Lati k’ajinde Re