Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 329

Kiyesi i, Emi mbe laye titi lae Amin.

Meter: 7.8.7.8.4.

Scripture: Ifi. 1:18.

1

fJesu ye titi aye,

Eru iku ko ba mi mo;

Jesu ye; nitorina

Isa oku ko n’ipa mo — Aleluya.

2

mfJesu ye, lat’ oni lo,

Iku je ona si iye;

Eyi y’o je ’tunu wa

’Gbat’ akoko iku ba de — Aleluya.

3

mpJesu ye; fun wa lo ku,

Nje Tire, ni a o ma se;

crA o f okan funfunsin,

A o f ogo fOlugbala — Aleluya.

4

Jesu ye; eyi daju,

Iku at’ipa okunkun

Ki yo le ya ni kuro

Ninu ife nla ti Jesu — Aleluya.

5

Jesu ye; gbogbo ’joba

L’orun, li aye, di Tire;

mfEje kia ma tele,

crKi a le joba pelu Re— Aleluya.