Hymn 330
Wo o, Jesu pade won, O wipe Alafia
Meter: 7.6.7.6.D.
Scripture: Mat. 28:9.
1
fEyi l’ojo ajinde,
Wi kakiri aye;
Irekoja didun ni,
T’Olorun Olore;
Lat’ Inu iku s’iye,
Lat'aye si orun,
ffNi Krist’ ti mu wa koja,
Pel’ orin isegun
2
mfOluwa we okan wa,
Ko ba le mo toto;
Ka ba le ri Oluwa
N’nu ’mole ajinde;
crKa si feti sohun Re
Ti ndun lohunjeje,
Pe “Alafia fun yin”
Ka nde, ka si tele.
3
fEyin orun, bu sayo
K’aye bere gberin;
Ki gbogbo aye yika
Dapo lati gberin;
Eda nla ati wewe,
E gbohun yin soke,
ff’Tori Kristi ti jinde,
Ayo wa ki yo pin.