Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 331

Mo si ni kokoro iku ati ti ipo oku

Meter: 11.11.11.11. & Ref.

Scripture: Ifi. 1:18.

1

fK abo ojo rere l’ao ma wi titi;

Asete ku loni orun di tiwa,

’WO oku d’alaye, Oba tit’aye,

Gbogb’ eda Re, Jesu, ni nwon njuba Re.

CHORUS

ff“Kabo ojo rere,” lao ma wi titi

A sete ku loni, orun di ti wa.

2

mfEleda, Oluwa, Emi alaye!

Lat’orun l’O ti b’ojuwo ’sina wa;

Om’Olorun papa ni ’Wo tile se,

K’O ba le gba wa la; O di eniyan.

3

mf’WO Oluwa iye, O wa to ’ku wo;

Lati fipa Re han, O sun n’iboji;

Wa, Eni Oloto, Si m’oro Re se,

OJO keta Re de, jinde Oluwa!

4

mfTu igbekun sile, t’esu de l’ewon,

Awon to si subu, jo gbe won dide.

F’oju rere Re han, je k’aye riran,

Tun mu mole wa de, ’WO sa ni ’Mole.