Hymn 335
Eniti O tun wa bi sinu ireti aye nipa ajinde Jesu.
Meter: 8.7.8.7.D.
Scripture: I Pet. 1:3.
fAleluya, Aleluya,
E gbe ohun ayo ga,
E ko orin inu didun
K’e si yin Olorun wa;
pEni t’a kan m’agbelebu
T’O jiya fun ese wa,
ffJesu Kristi, Oba Ogo
Jinde kuro n’nu oku.
fIrin idabu se kuro,
Kristi ku, O si tun ye;
O mu iye ati aiku
Wa loro Ajinde Re;
Krist’ ti segun, awa segun
Nipa agbara nla Re
ffAwa o jinde pelu Re
A o ba wo ’nu ogo.
mfKristi jinde, akobi ni
Ninu awon t’o ti sun;
Awon yi ni y’o ji dide
Ni abo Re ekeji;
Ikore ti won ti pon tan,
Won nreti Olukore,
Eni ti y’o mu won kuro
Ninu isa oku won.
mfAwa jinde pelu Kristi,
T’O fun wa l’ohun gbogbo,
Ojo, iri, ati ogo
T’o ntan jade l’oju Re;
Oluwa ba ti wa l’aye,
Fa okan wa s’odo Re
crK’awon angeli sa wa jo
Ki won ko wa d’odo Re.
ffAleluya, Aleluya,
Ogo ni fun Olorun;
Aleluya f Olugbala
Enit’ t’O segun iku;
Aleluya, f’Emi Mimo
Orisun ’fewa mimo;
Aleluya, Aleluya
F’Olorun Metalokan.