Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 336

Emi li Eniti O mbe laye ti o si ti ku; si kiyesi i, Emi si mbe laye titi lae — Amin.

Meter: L.M.

Scripture: Ifi. 1:18.

1

pJesu, Ore elese ku,

Awon omo Salem nsokun,

Okunkun bo oju orun,

Isele nla se lojiji.

2

pEyin Mimo, e wa sokun,

Eni t’O jiya n’tori yin;

ppOn sokun kikoro fun yin,

O ta ’je Re Owon fun yin.

3

mpIfe at’edun yi l’eke;

Oba ogo ku fun eda;

Wo ayo airotele de;

Jesu t’O ku, si tun jinde!

4

crOlorun ko ’boji sile,

’Boji ko le da ’jinde ro!

Ogun angel sin LO s’ile;

Won fayo gba soke orun.

5

fMa sokun mo, eyin mimo,

E so p’Olugbala joba,

E korin ti isegun Re

fL’ori esu ati iku.

6

fE wipe, “Oba pe titi”,

IWO ta bi lati gba wa,

E bi ’ku pe “Oro re da?”

“Iboji, isegun re da.”