Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 339

Tali Oba ogo yi? Oluwa awon omo ogun; On na li Oba Ogo.

Meter: 10.10.10.10. & Ref.

Scripture: OD. 24:10.

1

fKe Kabiyesi! gbe ilekun soke;

Lenu ona re Oba Ogo nduro!

Si okan re, sile ese jade,

Dide jeki Oba Ogo wole.

CHORUS

ffTali On? Tal’Oba Ogo yi?

Jesu Oluwa li ola ye fun

Ke Kabiyesi! Wole n’waju Re

Se l’Oba, l’Oba Oba gbogb’eda.

2

mfLati agbala orun lojo na,

O Sokale ni ara erupe;

Fun wa n’ijiya, ibanuje Re,

Ise irora ati ekun Re.

3

mpA kan mo ’gi ika ati ’tiju

F’eje Re ta ta ’le lo se w’aye;

Gbo lat’enu Re igbe irora,

Nitori wa l’Olugbala se ku.

4

fIku ko le bori Re niboji,

Lowuro lo jade kuro nibe,

O ji dide, O njoba ni oke,

Ki gbogb’aye fiyin fun Oluwa.