Hymn 341
O si wi fun awon omo ehin pe, On ti ri Oluwa.
Meter: 7.7.7.7.
Scripture: Jn 20:18
1
fOrun, korin! Aye, yo
Anglei at’eniyan
E yi ka b’O ti ndide,
E gbe ‘yin Jesu yin ga.
2
fA ti fo ejo l’ori
A segun ‘ku at’Esu,
Labe Jesu t’O goke,
A ti mu ‘gbekun l’eru
3
fIse at’ija Re tan,
O lo sinu ayo Re,
O si mbe f’awon Tire,
Nibi ite Baba Re.