Hymn 342
E yara lo so fun awon omo ehin Re pe, O Jinde.
Meter: C.M.
Scripture: Mat. 28:7.
1
mfMo wi fun olukuluku
fPe, On ji, Osi ye;
O si wa larin wa pelu,
Nipa emi iye.
2
E wi fun enikeji yin,
Ki won ji pelu wa,
K’imole k’o wa kakiri
Ni gbogbo aye wa.
3
Nisisiyi aye yi ri
Bi ile Baba wa:
Iye titun ti On fun ni,
O so d’ile Baba.
4
mfOna okun ti On ti rin
Mu ni lo si orun;
Eni t’o rin bi On ti rin.
Y’o d’odo Re l’orun.
5
fOn ye, O si wa pelu wa,
Ni gbogbo aye yi;
Ati nigbat’ a f ara wa,
F’erupe ni ’reti.