Hymn 345
Kristi ti jinde kuro ninu oku
Meter: S.M.
Scripture: I. Kor. 15:20.
1
f“O luwa ji loto,”
Ihin na ha s'oto?
pWon ti ri p’Olugbala ku,
crWon ri l’aye pelu.
2
f“Oluwa ji loto”
Oto ko fe ju yi;
Anu at’otito pade,
Ti won ti ns’ota ri.
3
f“Oluwa ji loto,”
Ise Re l’o setan;
fA da ide onigbowo,
A se apa iku.
4
f“Oluwa ji loto,”
mfBoji ko le se mo;
Awon t’o ku si ji pelu,
crWon ki o si ku mo.