Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 346

Nigbati nwon wo inu iboji, nwon ko Si ba oku Jesu Oluwa.

Meter: 6s. 8s.

Scripture: Lk. 24:3

1

fO luwa ji loto

Olugbala dide,

O f’agbara Re han;

L’or’orun apadi:

N’iberu nal: awon eso

Subu lule won si daku

2

Wo, egbe Angeli

Pade l’ajo kikun:

Lati gbo ase Re

Ati lati juba;

Won fayo wa, won si nlo lo,

Lati orun s’iboji na.

3

Won tun fo lo s’orun.

Won mu ‘hin ayo lo;

Gbo iro orin won,

Bi won si ti nfo lo

Orin won ni Jesu to ku

Ti ji dide; O ji loni.

4

Eyin t’a ra pada

Egberin ayo na:

Ran iro re kiri'

Si gbogbo agbaye

E ho fayo Jesu t’O ku

Ti ji dide: ki y’o ku mo

5

Kabiyesi! Jesu!

T’O f’eje Re gba wa

Ki iyin Re kale

Iwo t’O ji dide

Aba O ji asi joba,

Pelu Re lai; loke orun.