Hymn 349
Ago Re wonni ti lewa to?
Meter: 7.7.7.7.D.
Scripture: OD. 84:1.
1
fBugbe Re ti l’ewa to
N’ile ’mole at’ife!
’Bugbe Re ti l’ewa to
L’aye ese at’osi!
Okan mi nfa ni toto
Fun idapo eeyan Re
Fun imole oju Re
Fun ekun Re Olorun.
2
fAyo ba awon eye
Ti nfo yi pepe Re ka,
Ayo okan t’o nsimi
L’aya Baba l’o poju,
Gege b’adaba Noa
Ti ko r’ibi simi le,
Won pada s’odo Baba
Won si nyo titi aye.
3
fWon ko simi iyin won
Ninu aye osi yi;
Omi sun ni aginju,
Manna nt’orun wa fun won
Won nlo lat’ipa de ’pa
Titi won fi yo si O;
Won si wole l’ese Re
T’o mu won la ewu ja.
4
mfBaba, je ki njere be;
crS’amona mi l’aye yi;
F’ore-ofe pa mi mo;
Fun mi l’aye l’odo Re;
IWO l’orun, at’asa;
To okan isina mi,
IWO l’orisun ore,
RO ojo Re s’ori mi.