Hymn 354
Jesu na yi, ti a gba soke orun yio pada be, bi e ti rii ti o nlo si orun.
Meter: 6.6.6,6.8.8.
Scripture: Ise. A . 1:11.
1
mfEyin t’e fOluwa,
To mo ’pa Re, e wa,
E dapo n’isokan,
Lati yin ore Re,
F’orun at’aye, e kede
Oruko Oludande yin.
2
O rite Re l’oke
At’ogo Re sile;
O fife sokale,
O sokun, O si ku;
Iya to je tani le wi
Lati gb’okan wa lowo iku?
3
Lati’boji; O nde
N’isegun lor’iku;
O k’awon ota Re,
To segun lat’ibe;
O si l’awon orun koja
N’isegun s’ite Olorun.
4
O fere pada wa,
Keke Re ki yo pe,
Lati m’omo Re LO
Si ile ailopin;
Nibe l’ao ri lojukoju,
L’ao ko isegun ore Re.
5
Jesu, a ko le san
Gbese ’fe Re ta je,
KO wa ba ti le san;
Gba ’yin at’ope wa,
T’okan t’ara wa la fun O;
Bo tile kere, te ’WO gba.