Hymn 355
OWO otun Re, ati apa Re mimo, Li o ti mu igbala wa fun ara Re.
Meter: 8.7.8.7. D.
Scripture: OD. 98:1.
fWo Asegun b’O ti g’oke,
Wo Oba n’nu ola Re;
Ogun keke ofurufu
LO s’orun agbala Re;
Gbo orin awon angeli
Aleiuya ni nwon nko,
Awon ’lekun si si sile,
Lati gba Oba orun.
mfTani ologo ti mbo yi,
T’On ti ipe Jubeli
pOluwa awon ’mo-ogun,
On t’O ti segun fun wa
pO jiya lor’agbelebu
O jinde ninu oku,
fO segun esu at’ese
Ati gbogbo ota Re.
mfBo ti nbuk’awon ore Re,
A gba kuro lowo won.
Bi oju won si ti nwo LO,
O nu nin’awo sanma;
Eni t’O ba Olorun rin
To si nwasu otito,
On, Enok’ wa li a gbe LO
S’ile Re loke Orun.
mpOn Aaron wa gbe eje Re
WO inu ikele lo;
Joshua wa ti wo Kenan’
Awon Oba nwariri;
mfA fi di eya Israel’
Mule nibi ’simi won,
Elija wa si fe fun wa
N’ilopo meji Emi.
fIwo ti gbe ara wa WO
Lo s’ow’Otun Olorun;
A si joko nibi giga
Pelu Re ninu ogo;
ffAwon angeli mbo Jesu
Eniyan joko lor’ite;
Oluwa, b’Iwo ti goke
Jo je ka le goke be.