Hymn 356
Nigbati Oluwa si ti ba won soro tan, a si gba A lo soke orun.
Meter: 7.7.7.7. & Aleluya
Scripture: Mk. 16:19.
fAlafia f Ojo na - Aleluya
T’O pada s’ite lorun - Aleluya
pKrist’ t’a ti fifun eda - Aleluya
fTun pada soke orun - Aleluya
ffIyin duro de nibe - Aleluya
Gb’ori s’oke, ilekun - Aleluya
Si ogo orun paya - Aleluya
Je k’Oba ogo wole - Aleluya
fOrun, gba Oluwa re - Aleluya
mpSibe On feran aye - Aleluya
fBo ti pada s’ite Re - Aleluya
mpSibe O pe wa n’Tire - Aleluya
mpWo! O gbowo Re soke - Aleluya
Wo! O fapa ife han - Aleluya
Gbo, bi O ti nsure fun - Aleluya
Ijo Re l’aye nihin - Aleluya
mfSibe O mbebe fun wa - Aleluya
Ebe Re yo si bori - Aleluya
crO npese aye fun wa - Aleluya
fOn l’akobi iran wa - Aleluya
crOluwa lae lao ma ke - Aleluya
S’Iwo ti a gba soke - Aleluya
Pe, wo awa ’ranse Re - Aleluya
Ba ti te ’ju wa mo O - Aleluya
Bo ti je pe agba O - Aleluya
Soke kuro lodo wa - Aleluya
Jo, je k’okan wa dide - Aleluya
Ba O lo soke orun - Aleluya
Nibe lao wa pelu Re - Aleluya
N’ijoba ayeraye - Aleluya
Nibe l’ao ri oju Re - Aleluya
Li orun awon orun - Aleluya