Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 360

A gbe E soke; awosanmo si gba A kuro li oju won.

Meter: 7.7.7.7.D.

Scripture: Ise A. 1:9.

1

pO ti lo, awosanmo

Ti gba kuro loju wa

fSoke orun, nibiti

Oju wa ko le tele;

O ti kuro l’aye yi,

O ti de ibi mimo,

Lala ati ’rora tan,

Ija tan, O si segun.

2

pO ti lo, awa si wa

L’aye ese at’ iku,

A ni ’se lati se fun,

L’aye to ti fi sile

crKa si tele ona Re;

Ka tele tokan tokan,

Ka s’ota Re di ore,

Ka fi Krist’ han n’iwa wa.

3

pO ti lo, On ti wipe,

“Odara ki Emi lo”

Ni ara sa lo ya wa,

Sugbon or’ofe Re wa,

mfOn ni awa ko ri mo

A ni olutunu Re;

fEmi Re si jo ti wa,

O ns’agbara wa d’otun.

4

pO ti lo, l’ona kanna

Lo ye k’Ijo Re ma LO

Ka gbagbe ohun ehin

fKasi mate siwaju,

Oro Re ni ’mole wa

Titi de opin aye

Nibiti oto Re wa

Yo pese fun aini wa.

5

pO ti lo l’ekan si i

A o tun foju wa ri;

O wa bakanna lorun

Gege b’o ti wa l’aye;

N’nu ’bugbe to wa nibe

Yo pese aye fun wa;

pNinu aye ti mbo wa

A o j’okan pelu Re,

6

pO ti lo fun ire wa,

E jeki a duro de,

fO jinde ko si nihin,

Oti goke re orun,

Je ka gb’okan wa soke

Sibiti Jesu ti lo,

Si odo Olorun wa.

ffNibe l’alafia wa.