Hymn 369
Emi o si bere lowo Baba On o si fun nyin li Olutunu miran ki o le ba nyin gbe titi.
Meter: 8.6.8.4.
Scripture: Jn. 14:16,
1
mpOlurapada wa, k’On to
Dagbere ikehin,
O fi Olutunu fun ni,
Ti mba wa gbe.
2
pO wa ni awo adaba,
O na iye bo wa;
Otan ’fe on alafia
S’ori aye.
3
mfO de, O mu ’wa rere wa,
Alejo Olore;
’Gbat’ O ba r’okan irele
Lati magbe.
4
pTire l’ohun jeje tangbo,
Ohun kelekele;
Ti mbani wi, ti nl’eru lo
Ti nso t’orun.
5
Gbogbo iwa rere ta nhu
Gbogbo isegun wa;
Gbogbo ero iwa mimo
Tire ni won.
6
mfEmi Mimo Olutunu,
Fi ’yonu be wa wo,
crJo s’okan wa ni ’bugbe
Re Koye fun O.