Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 372

Emi Olorun si nra baba loju omi.

Meter: 8.8.8.D.

Scripture: Gen. 1:2.

1

mfEmi Eleda, nipa Re

La f’ipile aye sole;

pMa sai be gbogbo okan wo,

Fi ayo Re si okan wa,

YO wa nin’ese at’egbe,

Ko fi wa se ibugbe Re.

2

fOrisun imole ni O,

Ti Baba ti se ileri

IWO ina mimo orun

F’ife orun kun okan wa;

pJo tu ororo mimo Re

S’ori wa bi a ti nkorin.

3

mpDa opo ore-ofe Re

Lat’ orun s’ori gbogbo wa;

crJe ka gba otito Re gbo,

Ka si ma saro l’okan wa;

F’ara Re han wa ka le ri

Baba at’Omo ninu Re.

4

fKa fi ola ati iyin

Fun Baba, Olodumare,

Ka yin oko Jesu logo;

Eni t’O ku, lati gba wa;

Iyin bakanna ni fun O

Parakliti ayeraye.