Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 376

lye awon ti a fi Emi Mimo Olorun to, awon ni ise omo Olorun.

Meter: L.M.

Scripture: Rom. 8:14.

1

mfEmi Mimo’Daba orun,

Wa mu itunu sokale;

fSe oga at’Oluto wa,

Ma pelu gbogbo ero wa.

2

mfJo fi otito Re han wa,

Ka le fe, ka si m’ona Re,

pGbin ife toto s’okan wa,

Ka ma le pada lehin Re.

3

crMu wa ka to ona mimo;

Ta le gba d’odo Olorun:

Mu wa to Krist’ ona iye,

Maje ki awa sina lo.

4

fMu wa t’Olorun ’simi wa,

Ka le ma ba gbe titi lae;

To wa s’orun, ka le n’ipin

L’OWO Otun Olorun wa.