Hymn 378
Emi o dabi iri si Israeli.
Meter: 7.7.7.6.
Scripture: Hos. 14 : 5
mfEmi ’bukun ti a nsin
Pelu Baba at’oro,
Olorun ayeraye;
pGbo wa, Emi mimo.
crIwo Adaba orun
Iri ti nse lat’ oke;
Emi ’ye at’ina ’fe,
pGbo wa, Emi mimo.
mfIsun, ipa at’imo,
Ogbon at’iwa-mimo,
Oye, imoran, eru;
pGbo wa, Femi mimo
mfIsun ife alafia,
Suru ’bisi igbagbo,
’Reti ayo ti ki tan,
pGbo wa, Emi mimo
crEmi afona han ni,
Emi ti nmu ’mole wa,
Emi agbara gbogbo
pGbo wa, Emi mimo.
mp’Wo t’O mu Wundia bi,
Eni t’orun, t’aye mbo,
Ta ran lati tun wa bi,
pGbo wa, Emi Mimo.
cr'WO ti Jesu t’oke ran
Wa tu eniyan Re ninu,
Ki nwon ma ba nikan wa,
pGbo wa, Emi mimo.
’Wo t’On fore kun Ijo,
T’O nfi ife Baba han,
T’O nmu ko ma ri Jesu,
pGbo wa, Emi mimo.
mfIWO ti n f’onje iye
At’otito na bo wa
Ani, On to ku fun wa
pGbo wa, Emi mimo
mfF’ebun meje Re fun ni,
Ogbon lati m’Olorun,
Ipa lati ko ota,
pGbo wa, Emi mimo
mfPa ese run l’okan wa,
TO ife wa si ona,
Ba ba nse O mu suru;
pGbo wa, Emi mimo.
crGbe wa dide, ba subu,
Ati nigba idanwo,
Sa pe wa pada pele
pGbo wa, Emi mimo
mfWa k’O mu ailera le,
F’igboya fun alare,
KO wa l’oro ta o so;
pGbo wa, Emi mimo.
mfWa ran Okan wa lowo,
Lati mo otito Re,
Ki ’fe wa le ma gbona,
pGbo wa, Emi mimo.
mfPa wa mo l’ona toro,
Ba wa wi ’gba ba nsako
Ba wa bebe l’adura,
pGbo wa, Emi mimo.
mfEmi Mimo, Olufe,
Wa gbe inu Okan wa;
Ma fi wa sile titi,
pGbo wa, Emi mimo.