Hymn 379
Sugbon enyin o gba agbara nigbati Emi Mimo ba ba le yin.
Meter: S.M.
Scripture: Ise A. 1:8
1
mfEmi alagbara,
Wa joko ninu mi,
Ki O si fun wa n’idande
Low’eru on ese
2
crEmi im’arale,
Gbe arun ese lo,
Emi iwa mimo pipe
Emi ife pipe
3
M’ojo na yara de
Ti ao run ese mi,
Ti ohun atijo yo koja,
T’ohun gbogbo d’otun
4
diEse abinibi,
Pare li okan mi;
crWole, ki O si le jade,
Gba gbogb’okan mi kan.
5
mfOluwa, mo fe ni,
Eri pe, mo nse ’re
Gegebi ’fe at’oro Re
Bo ti to l’oju Re.
6
di’Ko fe ipo giga;
Sa fi eyi ke mi,
Ni ’gbakugba to ba si ya,
pGbami s’orun rere.