Hymn 381
Ki ise ami ati ise iyanu ki o ma se li Oruko Jesu
Meter: 8.8.8.8.8.8.
Scripture: Ise A. 4:30.
1
mfAwa pejo s’iwaju Re
Lati kede ’gbala kikun;
Lati jewo ore ta gba
Nipa Oruko nla Jesu;
Tewo gb’ope wa, Oluwa
Te ongbe okan wa lorun.
2
mpAwa mbe O, lakoko yi
F’agbara Pentikpsti han;
’Gbati awon ti ongbe ngbe
Ri ’dariji on ’wenumo,
La oju awon afoju,
Si eti awon to di ’ti.
3
pAwon ti eru ese npa
Mbe nihin lati gba ’wosan;
Gbogbo awon ta npon loju
Lo wa fun idasile won
Soro ’wosan ki gbogbo won
Le gba iwenumo okan.
4
fF’igboya fawon ’ranse Re
Ki won wasu tokan tokan;
Na owo Re lati wosan
K’ise ‘yanu se l’oko Re,
Ka ri agbara Re loni
Ka le gbe oruko Re ga.
5
crAwa nduro bi O ti wi
Je ko ri fun wa b’oro Re,
K’aigbagbo tab’ igberaga
Mase dena agbara Re,
Joba ninu okan gbogbo,
Awa mbe O. Emi Mimo