Hymn 382
Emi o da omi lu eniti ongbe ngbe
Meter: 8.7.8.7.D. & Ref.
Scripture: Isa. 44:3.
1
mfAwa pejo l’oruko Re
Ninu ile mimo yi.
Ibukun Baba wa la n fe,
A mbere or’ofe Re;
Lat’ inu ekun ’bukun Re
Tio jin ju okun lo,
RO ojo na si wa lori
Ko fi so wa d’omnira.
CHORUS
fSi ferese orun sile
Ro ojo na s’ori wa;
Ro ojo igbala kikun,
We gbogbo abawon nu.
2
fSi ferese orun sile,
RO ojo na sori wa,
Yo wa kuro n’nu iparun,
Gbe wa soke to ga ju;
Ki opo awon elese
Le wa to ife Re wo;
Ka gba won sinu ’joba Re
Nipa ’wenu atunbi.
3
fAwa gbagbo pe O mbowa,
Ojo ’bukun na nbowa;
Iwo eniti ngbadura,
Na apa agbara Re,
Ojo agbara lat’oke
Ojo ife Kalfari;
Mu ago wa kunwo sile,
Ro ojo nla lat’oke.