Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 384

Nitoripe Olorun wa, ina ti ijonirun ni.

Meter: 11.10.11.10.

Scripture: Heb. 12:29.

1

mfIna Emi orun, ma jo ninu mi,

Da 'na iwa mimo si okan mi

Orisun ’mole at’ibukun gbogbo,

So aye mi di t’imole titi.

2

crIna Emi Orun, je k’ogo Re tan,

S’okan mi di mimo fun ogo Re;

Wa da ’na ife orun si okan mi

Ife ti njere okan f’Oluwa.

3

Ina Emi orun, ba le mi loni,

Ela ahon bi t’ina ba le mi,

Mu eyin-ina lati pepe orun;

Fi kan mi l’enu ki njise fun O,

4

fIna Emi Orun, ni igba meje

We mi, tun mi we, ki nle r’oju Re;

Titi aworan Re yo han lara mi

Ki nle ri iran Kristi ju be LO

5

ffIna Emi Orun f’ife Re kun mi,

Ki gbogbo aye mi le di Tire;

Emi, okan, ara mo fi won rubo.

Ran ina sori ebo na loni.