Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 398

Nitori ajaga mi rorun, Eru mi si fuye.

Meter: 7.7.7.7. & Ref.

Scripture: Mat. 11:30.

1

fJesu y’o gba elese

Kede re fun gbogb’eda;

diAwon ti won sako lo,

Awon ti won ti subu.

CHORUS

ffKo l’orin, ko si tun ko

Kristi ngb’awon elese

Fi oto na ye won pe:

Kristi ngb’awon elese

2

fWa, y’o fun o ni’simi;

Gbagbo, Oro Re daju,

Y’o gba eni buru ju;

Kristi ngb’awon elese

3

crOkan mi da mi lare,

Mo mo niwaju ofin;

Eni t’O ti we mi mo,

Ti san gbogbo gbesemi.

4

fKristi ngb’awon elese

An’emi to kun fese

O ti so mi di mimo;

Mo ba wo ’joba Orun;