Hymn 4
Ma rin niwaji mi, ki iwo ki o si pe.
Meter: L.M
Scripture: Gen. 17:1
1
mfOluwa mi, mo njade lo,
Lati se ise oojo mi;
Iwo nikan l’emi o mo
Loro, lero, ati n’ise
2
Ise t’o yan mi l’anu Re,
Jeki nle se tayo tayo,
Ki nr’oju Re n’nu ise mi,
K’emi si le fi ‘fe Re han
3
Dabobo mi lowo danwo,
K’opa okan mi mo kuro
Lowo aniyan aye yi
Ati gbogbo ifekufe.
4
crIwo t’oju Re r’okan mi,
Ma wa l’ow’otun mi titi,
Ki nma sise lo l’ase Re,
Ki nfise mi gbogbo fun O.
5
mfJe ki nreru Re t’o fuye,
Ki nma sora nigba gbogbo
Ki nma f’oju si nkan t’orun
Ki nsi mura d’ojo’ogo.
6
fOhunkohun t’O fi fun mi,
Je ki nle lo fun ogo Re,
Ki n f’ayo sure ije mi,
Ki nba O rin titi d’orun