Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 40

Eniti enyin fe lairi.

Meter: D.S.M

Scripture: 1 pet 1:8

1

fEyin t’e f’Oluwa,

E fi ayo yin han;

E jumo ko orin didun

B’e ti ny’ite Re ka;

Jek’awon ‘ni dake

Ti ko m’Olorun wa;

Sugbon k’awon ‘ranse Oba

Ma ro ayo won ka.

2

Olorun t’o joba,

Ti nwo gbogbo aye

Ti ngu awosanmo l’esin

Ti nmu ‘ji pa roro;

FfTiwa l’Olorun yi

Baba Olufe wa;

Y’o ran agbara t’orun wa

Lati gbe wa soke

3

mfNibe, l’ao r’oje Re,

T’a ki o dese mo;

T’ao si ma jadun ailopin,

Nipa or’ofe Re;

CrLoto, k’a to jinde

Si iye ailopin,

Ero irora nlanla na

FNinu Ayo wa bi si.

4

Eni-or’ofe ri

‘Bere ogo laye;

Eso orun ngberu laye

N’nu gbagbo on ‘reti:

CrNje k’orin wa goke,

K’omije gbogbo gbe;

FA nkoja lo n’le ‘manuel’

S’aye rere loke.