Hymn 400
Okan mi ti mura, Olorun okan mi ti mura.
Meter: 10.6.10.6. & Ref.
Scripture: OD. 57 : 7.
1
mfOkan mi, a tun fi Jesu lo o
L’ekan si n’nu oro Re,
Nisisiyi, Oluwa, un o pinnu
Nki o ha gba Tire?
CHORUS
Mo fe, mo fe
B’Olorun se ’ranwo
Emi fe je tire
Eje Re ’yebiye lo fi ra mi,
Emi yo je Tire
2
mfNipa or’-ofe l’em’o r’anu gba,
Mo jere ife Re.
Kristi IWO li emi o gbagbo,
Uno si gbekele O.
3
mpOluwa, IWO MO ailera mi
Bi nko ti fe sako,
’WO nikan lo le fun mi l’agbara
Lati josin fun O.
4
Oluwa f or’ofe fun wa loni
Ka le jumo'korin:
Ki gbogbo wa SO tokantokan pe,
Emiyo je ti Krist’.
5
mfAwon to t’o O wa nigba aye Re
Lati toro ’bukun,
“Mo fe” ni idahun ti won ri gba:
On na la gbokan le.