Hymn 405
Emi wa pelu nyin nigbagbogbo.
Meter: 8.7.8.7. & Ref.
Scripture: Mat. 28:20
1
Onisegun nla wa nihin,
Jesu abanidaro;
Oro Re mu ni l’ara da,
A gbo ohun ti Jesu.
CHORUS
fIro didun l’orin Seraf’,
Oruko didun li ahon;
Orin to dun julo ni:
diJesu, Jesu, Jesu
2
mpA figbogb’ese re ji o,
A gbo ohun ti Jesu.
crRin lo s’orun l’alafia
Si ba Jesu de ade.
3
fGbogb’ogo fun Krist’ t’O jinde
Mo gbagbo nisisiyi;
Mo f’Oruko Olugbala,
Mo fe Oruko Jesu.
4
Oruko Re l’eru mi lo,
Ko si oruko miran:
B’okan mi ti nfe lati gbo
Oruko Re ’yebiye
5
fArakunrin eba mi yin,
E yin oruko Jesu;
Arabirin, gb’ohun soke,
E yin oruko Jesu.
6
Omode at’agbalagba
T’o fe oruko Jesu
Le gba pe ’fe nisisiyi
Lati sise fun Jesu.
7
Nigbat’ a ba si de orun
Ti a ba si ri Jesu;
A o ko ’rin yi ’te ife ka,
Orin oruko Jesu.