Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 410

O je ki o mu oyin lati inu apata wa.

Meter: 11.10.11.11. & Ref

Scripture: Deut. 32:13

1

pN in’ aginju ese, Jesu wa mi ri,

Ninu ogbun ese. ainireti;

Jeje lona idariji l’O nto mi,

O si nfi onje bo mi li aginju.

CHORUS

mfPel’oyin ’n’apata lo fi mbo awon Tire,

Oyin didun lati ’nu apata,

Pel’oyin ’n’apata l’O fi mbo awon Tire,

Didun l’ebun olprun.

2

fNinu oro ore ofe lo nfun mi

Ni ’bukun ’yanu lo mayo mi kun,

’ Jojumo lo nfi ’sura Re bokan mi

Oyin, waru at’eso to daraju.

3

ffA ko le so gbogb’ayo ti 'rapada,

A ko le so ‘daji ’sura’bukun;

A ko le so won ’bukun to wa n’nu nini

Imo 'dariji at’alafia lae.

4

mpWa, elese, ipe nla ni eyi je,

Wa pel’okan t’eru npa;

Ki o ba le ni ipin ninu ayo

Ta se l’eri re fun awon oloto.