Hymn 416
E mase fe aiye.
Meter: C.M.
Scripture: 1 Jn. 2:15
1
mfAwa fe ohun aye yi,
Won dara l’oju wa;
A fe k’a duro pe titi
Laifi won sile lo
2
Nitori kini a nse bee?
Aye kan wa loke;
Nibe l’ese on buburu
Ati ewu ko si.
3
Aye t’o wa loke orun,
Awa iba je mo!
Ayo, ife, inu rere,
Gbogbo re wa nibe
4
pIku, o wani aye yi;
Ko si loke orun;
Eniyan Olorun wa mbe,
Ni aye, ni aiku.
5
K’a ba ona ti Jesu lo,
Eyi t’O la fun wa;
ffSibi rere, sibi ’simi,
crS’ile Olorun wa.