Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 425

E ma po si i ni ife Oluwa nigba gbogbo.

Meter: L.M.

Scripture: IKor. 15:58

1

fMa sise lo, mase sare,

Fi ayo sise Baba re,

Bayi ni Jesu se l’aye:

Ko ha ye k’awa ko se be.

2

Ma sise lo ki se lasan,

Ofo aye l’ere orun:

Bi araye ko fe yin o.

Iyin Jesu ju t’eda lo.

3

fMa sise, l’ojojumo,

pOkunkun aye fere de;

fMura si ’se, mase s’ole,

Ko ba le gba okan re la.

4

pPupo, pupo l’awon to ku,

Ti won ko n’ireti orun,

Gbe ina ’gbagbo re, ma fi;

Ma fi si okunkun aye.

5

Ma sise lo, ma gbadura:

F’ogbon wa awon to sina;

Jade lo s’opopo ona,

Ro asako lati wole.

6

fMa sise lo, ma yo pelu

Lehin ise ’wo o simi;

O fere gb’ohun Jesu na;

ffY’O ke tantan pe, “Emi de”.