Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 427

Olorun tikarara si wa pelu wa li Olori wa.

Meter: 11.11.11.11

Scripture: IIKro. 13:12

1

ffGbo iro efufu lat’ ona jinjin,

O nsoro ’jakadi ti ogun mimo;

Olorun mbe fun wa. O ti soro Re,

O si nso gbogbo yin, Ojise orun.

2

mfLo! ’wo ihinrere, ma segun titi,

Okunkun ndimole ni gbogbo aye;

O sa wole fun O, ile won si wo,

Gbogb’eda bu jewo pe ’Wo l’Oluwa.

3

fOlugbala mimo ti njoba loke,

K’awon om’ogun Re ma ri O titi;

Je k’oro Re ma tan lat’ile de ’le,

Ki gbogbo agbaye teriba fun O.