Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 43

Oluwa yio fun ni li ore-ofe ati ogo: ko si ohun rere ti yio fa Sehin lowo awon ti nrin dede.

Meter: L.M

Scripture: OD 84:11

1

mpOluwa gbo adura wa

N’nu le Re l’ojo mimo li;

Bi ebo ope n’ile yi

K’orin wa je itewogba.

2

crOluwa, isimi Re dun

Sugbon t’oke ju t’aye lo; Sibe

Pelu ‘reti ayo

Li okan ongbe wa nsare.

3

mfKo si are, ko si ise,

Ese, iku ki y’o de ‘be,

Ohun irora ki y’o dun

Nibiti ahon aiku wa.

4

fKo si adagiri ota,

Isimi laisi aniyan,

Oju ojo ko su nibe,

Osan gangan ayeraye.

5

mfBere, Ojo t’a ti nreti,

Mo si aye irora yi,

Ao f’ayo rin l’ona t’ayo

Ao si sun ninu Oluwa