Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 431

On o joba lot'okun de okun.

Meter: L.M.

Scripture: OD. 72:8

1

fJesu yo joba ni gbogbo

Ibit’aba le ri orun:

’Joba Re yo tan kakiri,

’Joba Re ki o nipekun.

2

mfOn li ao ma gbadura si,

Awon oba yo pe l’Oba;

Oruko Re b’orun didun

Y’o ba ebo oro g’oke.

3

Gbogbo oniruru ede,

Yo fi ’fe Re korin didun;

pAwon omode yo jewo,

Pe ’bukun won t’odo Re wa.

4

f’Bukun po nibi t’On joba,

A tu awon onde sile,

Awon alare ri ’simi,

Alaini si ri ’bukun gba.

5

ffKi gbogbo eda ko dide,

Ki won f’ola fun Oba wa;

K’angel’ tun wa t’awon t’orin

Ki gbogb’aye jumo gberin.