Hymn 435
Kristi si ni ori Ijo Re
Meter: 7.6.7.6.D
Scripture: Efe. 5:23
fJesu Oluwa ni ’se
Ipinle Ijo Re,
Omi ati oro Re
Ni On si fi tun da;
O t’orun wa, O fi se
Iyawo mimo Re,
mpEje Re lo si fi ra
pTi O si ku fun un.
Nile gbogbo la sa won,
Sugbon won je okan;
Oluwa kan gbogbo kan
Ati baptisi kan:
fOruko kan ni won yin,
Onje kan ni won nje;
Opin kan ni won n lepa,
Nipa ore ofe
Bi aye tile nkegan,
’Gbat’ iyonu de ba:
B’ija on eko keko
Ba mu iyapa wa;
Awon mimo yo ma ke
fWipe, “yo ti pe to?”
Oru ekun fere di
Oro orin ayo.
diL’arin gbogbo’banuje
At’iyonu aye,
Onreti ojo ’kehin
Alafia lae lae;
Titi yo foju Re ri
Iran ologo na!
Ti ijo nla, asegun
Yo d’ijo ti nsimi.
mfL’aye yio ni’dapo
Pelu Metalokan;
Osi ni’dapo didun
Pel'awon to ti sun;
fA! alabukun mimo!
Oluwa fi fun wa,
Ka ba le ri bi awon,
Ka ba O gbe l’orun.