Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 437

Oluwa joba; ki aye ki oyo.

Meter: 7.7.7.7

Scripture: OD. 97:1

1

mfOluwa joba aye,

Korin ’yin, eyin eda;

E korin tayo-tayo,

Jesu Messiah joba!

2

fJesu la f’agbara fun,

Oluwa gbogbo aye,

Gbogb’ ekun y’o wole fun:

Esu , gbo, k’o wariri!

3

ffK’awon angel’ d’ohun po

Ki won se ajoyo na;

Ki won jumo yin Jesu

Ki won kede ’segun Re

4

mfB’omo okunkun sata,

Awon tiwa ju won lo

Olorun mbe ko si nkan;

Kristi mbe k’ota damu.

5

fE foju igbagbo wo,

B’awon oke ti mole;

Olorun mbe nitosi,

O fi ’mole yi wa ka.

6

mfOlugbala sokale,

O ntoka s’ade ’segun,

O npe wa sipo loke,

O fe wa j’asegun lo.