Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 438

Eni-nla ni Oluwa.

Meter: 7.6.7.6.7.7.7.6

Scripture: OD. 48:1

1

fEni nla l’Olugbala

Ninu olanla Re;

On l’awon torun njuba,

Ijo Re l’aye nyin;

Ni ilu Olorun wa,

Loke mimo Re laye,

mfKede oko Re k’aye

Fi titobi Re han.

2

crNitor’iseun ife Re,

A duro n’ile Re;

Nihin f’oto ’fe Re han,

F’ipa ’gbala Re han:

A mo ’yin Re l’oko Re,

Pipe ewa Re logo;

mpGbogbo aye yo jewo

Pe, mimo n’ise Re

3

mfIjo Re mbe lailewu,

O duro l’apata;

Gbogbo ’leri re daju;

Tani le si n’idi?

Kiyes’ awon ofin Re

So f’awon ’ran ti mbo, pe,

fIjo na ko le baje

Lagbara Oluwa.

4

fTiwa l’Olorun Sion,

A simi le’fe Re;

Amo p’O ndariji ni,

Ti Kristi li a se:

On y’o se Oluto wa,

Si Jerusalem titun;

mfOn l’Enit’a simile,

Titi ayeraye.